ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/14 ojú ìwé 5-6
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Tí Kò Fi Bẹ́ẹ̀ Mọ̀wé Kà Lọ́wọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Tí Kò Fi Bẹ́ẹ̀ Mọ̀wé Kà Lọ́wọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kọ́ Àwọn Tí Ò Fi Bẹ́ẹ̀ Mọ̀wé Kà Lẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa Ṣe Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
km 6/14 ojú ìwé 5-6

Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Tí Kò Fi Bẹ́ẹ̀ Mọ̀wé Kà Lọ́wọ́

1. Ìṣòro wo ló lè yọjú tá a bá fẹ́ kọ́ ẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

1 Àwọn tá à ń wàásù fún lè fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, àmọ́ Bíbélì tàbí àwọn ìwé míì lè kà wọ́n láyà tí wọn kò bá fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà. Tá a bá fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, pàápàá nígbà tá a kọ́kọ́ pàdé wọn, ohun tá à ń kọ́ wọn lè má tètè yé wọn. Báwo la ṣe lè kọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? A bi àwọn akéde tí wọ́n ní ìrírí, tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè tó lé ní ogún bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é. Ohun tí wọ́n sọ nìyí.

2. Àwọn ìwé wo la lè fi ran ẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà lọ́wọ́?

2 Tí akẹ́kọ̀ọ́ náà kò bá fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà tàbí tí kò lè kàwé rárá, a lè kọ́kọ́ fi ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Ohun tí aṣáájú-ọ̀nà kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà máa ń ṣe ni pé, ó máa fi àwọn ìwé méjèèjì han ẹni tó fẹ́ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, á sì ní kó mú èyí tó rọ̀ ọ́ lọ́rùn nínú méjèèjì. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní orílẹ̀-èdè Kenya sọ pé àwọn ìwé méjèèjì yìí wúlò gan-an lọ́dọ̀ àwọn, torí pé ní Áfíríkà ìtàn la sábà máa fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, kì í ṣe ká máa jíròrò nǹkan lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó kàwé lè tètè gbà pé ká fi ìlànà ìbéèrè àti ìdáhùn kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ ó lè ni ẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà lára. Tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá lè kàwé dé ìwọ̀n àyè kan, ọ̀pọ̀ akéde máa ń fẹ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìwé pẹlẹbẹ Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! tàbí O Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, wọ́n sì lè lo ìwé Ìtàn Bíbélì.

3. Kí la mọ̀ nípa àwọn tí kò mọ̀wé kà tó jẹ́ ká mọ bó ṣe yẹ ká kọ́ wọn?

3 Ẹ Máa Yìn Wọ́n: Ojú lè máa ti àwọn tí kò mọ̀wé kà, ọ̀pọ̀ nínú wọn sì máa ń ro ara wọn pin pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan. Ohun àkọ́kọ́ tó yẹ ká ṣe ká lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni pé ká jẹ́ kára tù wọ́n. Ọ̀pọ̀ àwọn tí kò lè kàwé máa ń jẹ́ onílàákàyè, wọ́n sì lè kẹ́kọ̀ọ́. Ẹ bọ̀wọ̀ fún wọn, ẹ má sì wọ́ wọn nílẹ̀. (1 Pét. 3:15) Wọ́n á máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nìṣó tí wọ́n bá rí i pé ìsapá wọn kò já sí asán, tí wọ́n sì tún rí i pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ ń yé wọn. Torí náà, ẹ máa yìn wọ́n.

4. Báwo la ṣe lè gba àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà níyànjú láti máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn sílẹ̀?

4 Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà kò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà, gbà á níyànjú pé kó máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn akéde kan ní orílẹ̀-èdè South Africa máa ń fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn níṣìírí pé kí wọ́n ní kí ẹbí wọn kan tàbí ọ̀rẹ́ wọn kan tó mọ̀wé kà dáadáa máa kà á sáwọn létí. Akéde kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì máa ń jẹ́ kí àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lo ìwé tirẹ̀ ní àwọn ìpínrọ̀ mélòó kan nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n lè rí i bó ti rọrùn tó láti rí ibi tí ìdáhùn wà téèyàn bá ti fàlà síbẹ̀, èyí sì máa ń jẹ́ káwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀. Arákùnrin kan ní Íńdíà máa ń fún àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ níṣìírí pé kí wọ́n wo àwọn àwòrán tó wà nínú ẹ̀kọ́ tí wọ́n máa kọ́ lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, kí wọ́n sì ṣàṣàrò lé wọn lórí ṣáájú.

5. Báwo la ṣe lè mú sùúrù tá a bá ń kọ́ ẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

5 Mú Sùúrù: Ìwé yòówù kẹ́ ẹ máa lò, mọ àwọn kókó tó ṣe pàtàkì níbẹ̀, kó o sì rí i pé akẹ́kọ̀ọ́ náà lóye rẹ̀ dáadáa. Ní ìbẹ̀rẹ̀, o lè jẹ́ kí ìjíròrò yín mọ sí bí ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Má ṣe jíròrò àwọn nǹkan tó pọ̀ jù, ìpínrọ̀ mélòó kan lè ti tó fún ìjókòó kan. Tí ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ń kà bá ń kọ́ ọ lẹ́nu, mú sùúrù fún un. Bó bá ṣe ń mọyì Jèhófà sí i, ó ṣeé ṣe kó túbọ̀ wù ú láti mọ̀wé kà. Tó o bá sì fẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọyì Jèhófà, àtìbẹ̀rẹ̀ ni kó o ti máa pè é wá sí ìpàdé.

6. Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀wé kà?

6 Bí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ti mọ̀wé kà, wọ́n máa yára tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. (Sm. 1:1-3) Tí akẹ́kọ̀ọ́ kan bá rẹ̀wẹ̀sì, o lè rán an léti àwọn nǹkan tó ti kọ́ tó sì ti mọ̀ ọ́n ṣe, èyí á jẹ́ kó gbà pé òun lè mọ̀wé kà. Jẹ́ kó dá a lójú pé Jèhófà máa bù kún ìsapá rẹ̀, kó o sì ní kó máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́. (Òwe 16:3; 1 Jòh. 5:14, 15) Àwọn akéde kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì máa ń sọ fáwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé kí wọ́n ní àfojúsùn tó bọ́gbọ́n mu tí ọwọ́ wọn lè máa tẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Wọ́n lè ní kí wọ́n kọ́kọ́ mọ gbogbo àwọn álífábẹ́ẹ̀tì, lẹ́yìn náà kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè wá àwọn ẹsẹ Bíbélì kan rí, kí wọ́n sì mọ̀ ọ́n kà. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n wá gbìyànjú láti máa ka àwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì lọ́nà tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọrùn. Ọ̀nà téèyàn lè gbà kọ́ àwọn míì láti mọ̀wé kà ni pé kéèyàn jẹ́ kó wù wọ́n láti mọ̀wé kà, kì í ṣe ka máa kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa kàwé.

7. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká lọ́ tìkọ̀ láti wàásù fún àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà?

7 Jèhófà kì í fojú ẹni yẹpẹrẹ wo àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ kàwé. (Jóòbù 34:19) Ọkàn onítọ̀hún ni Jèhófà ń wò. (1 Kíró. 28:9) Torí náà má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti kọ́ àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àwọn ìwé pọ̀ tó o lè lò. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, o lè wá lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni kí ẹni náà lè lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì dáadáa.

Ojú lè máa ti àwọn tí kò mọ̀wé kà, ọ̀pọ̀ nínú wọn sì máa ń ro ara wọn pin pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan. Ohun àkọ́kọ́ tó yẹ ká ṣe ká lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni pé ká jẹ́ kára tù wọ́n

Bí ẹni tó o fẹ́ wàásù fún kò bá mọ̀wé kà, gbìyànjú èyí wò:

  • Kọ́kọ́ lo ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run, Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, tàbí ìwé míì tó rọrùn láti kà.

  • Bọ̀wọ̀ fún un, kó o sì máa yìn ín.

  • Má ṣe jẹ́ kí ìjíròrò yín pẹ́ jù, má sì jẹ́ kí ìpínrọ̀ tẹ́ ẹ máa kà pọ̀ jù.

  • Ràn án lọ́wọ́ kó lè mọ̀wé kà dáadáa.

Bó ṣe túbọ̀ ń mọyì òtítọ́, tó sì ń wù ú láti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i, wàá lè bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́