ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/09 ojú ìwé 2
  • Kọ́ Àwọn Tí Ò Fi Bẹ́ẹ̀ Mọ̀wé Kà Lẹ́kọ̀ọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kọ́ Àwọn Tí Ò Fi Bẹ́ẹ̀ Mọ̀wé Kà Lẹ́kọ̀ọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Tí Kò Fi Bẹ́ẹ̀ Mọ̀wé Kà Lọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Káwọn Ọmọdé Máa Kàwé—Apá Kìíní: Ìwé Kíkà Tàbí Ìran Wíwò?
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Jíjàǹfààní Láti Inú Bibeli Kíkà Lójoojúmọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 4/09 ojú ìwé 2

Kọ́ Àwọn Tí Ò Fi Bẹ́ẹ̀ Mọ̀wé Kà Lẹ́kọ̀ọ́

1. Ìṣòro wo la lè bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá?

1 Tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá, a máa ń pàdé àwọn èèyàn tí ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà, ó sì máa ń ṣòro gan-an láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Kí la lè ṣe?

2. Báwo la ṣe lè fọ̀wọ̀ àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà wọ̀ wọ́n, kí sì nìdí?

2 Máa Fọ̀wọ̀ Wọn Wọ̀ Wọ́n: Ohun tó wà lọ́kàn ẹnì kan ló ṣe pàtàkì sí Jèhófà, kì í ṣe bónítọ̀hún ṣe kàwé tó. (1 Sám. 16:7; Òwe 21:2) Torí náà, a kì í tẹ́ńbẹ́lú àwọn èèyàn tí ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà. Àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè gba ìrànlọ́wọ́ wa tá a bá bọ̀wọ̀ fún wọn tá a sì fi sùúrù bá wọn lò. (1 Pét. 3:15) Èyí lè gba pé, ká má ṣe fi ọ̀ranyàn mú ẹni náà pé kó ka ẹsẹ Bíbélì tàbí ìpínrọ̀ kan. Bí ẹnì kan ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ òtítọ́, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí wù ú pé kóun mú kí ọ̀nà tóun gbà ń kàwé sunwọ̀n sí i, kó bàa lè ní ayọ̀ téèyàn máa ń rí nínú fífi “ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “tọ̀sán-tòru.”—Sm. 1:2, 3.

3. Oríṣiríṣi ọ̀nà wo lo lè gbà kọ́ àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà lẹ́kọ̀ọ́?

3 Oríṣiríṣi Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: Lílo àwòrán jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì téèyàn lè gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tónítọ̀hún ò sì ní gbàgbé. O lè ní kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ sọ bí àwòrán tó wà níbi tẹ́ ẹ kẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe yé e sí. Lẹ́yìn náà kó o wá béèrè ìbéèrè kan táá jẹ́ kẹ́ni náà mọ ohun tí àwòrán náà ń kọ́ni. Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ ohun tó o fẹ́ kó kọ́ látinú àwòrán náà. O tún lè lo àwòrán láti ṣàtúnyẹ̀wò ohun tẹ́ ẹ kọ́ lọ́jọ́ náà. Má ṣe ka ìpínrọ̀ tó pọ̀ jù lẹ́ẹ̀kan. Tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ àti kókó ẹ̀kọ́, má ṣe mú ọ̀rọ̀ míì wọnú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ jáde tààràtà látinú Bíbélì, kó o sì béèrè ìbéèrè tó máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá akẹ́kọ̀ọ́ náà lóye ẹsẹ Bíbélì tẹ́ ẹ kà. Èyí lè mú kó túbọ̀ fẹ́ láti mú kí ọ̀nà tó gbà ń kàwé sunwọ̀n sí i, kó bàa lè ṣe ìwádìí púpọ̀ sí i fúnra rẹ̀ nínú Bíbélì.

4. Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó lè mú ọ̀nà tó gbà ń kàwé sunwọ̀n sí i?

4 Àwọn Ohun Tó Lè Mú Kéèyàn Túbọ̀ Mọ̀wé Kà: Àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà tàbí tó jẹ́ pé wọn ò lè kàwé lọ́nà tó já geere sábà máa ń lóye nǹkan, wọ́n sì máa ń rántí nǹkan dáadáa. O lè ní kírú àwọn bẹ́ẹ̀ máa tẹ́tí sí àwọn ìtẹ̀jáde wa tá a gbohùn ẹ̀ sílẹ̀. Ní kó máa fọkàn bá ẹni tó ń kàwé yẹn lọ, kóun náà sì máa wo ohun tí wọ́n ń kà nínú ìwé tó wà lọ́wọ́ ẹ̀, ó tiẹ̀ lè máa fi ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ka ìwé náà tẹ̀ lé e, ìyẹn á ran ẹni náà lọ́wọ́ láti mú kí ọ̀nà tó gbà ń kàwé túbọ̀ já geere. Láwọn ibòmíì, àwọn alàgbà tún lè ṣètò kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà nínú ìjọ. Àwọn àbá tó gbéṣẹ́ yìí lè ṣèrànwọ́ fáwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà láti dẹni tó lóye “ìwé mímọ́” èyí táá sọ wọ́n di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.—2 Tím. 3:15.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́