Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Náhúmù
1. Kí la rí kọ́ látinú ìwé Náhúmù?
1 Àwókù ìlú Nínéfè ìgbàanì fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Náhúmù ṣẹ. Jèhófà gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tà Rẹ̀, kódà èyí tó rorò jù lára àwọn ọ̀tá Rẹ̀ kò lè kò Ó lójú. (Náh. 1:2, 6) Tí a bá fara balẹ̀ gbé àsọtẹ́lẹ̀ Náhúmù yẹ̀ wò, a máa rí ẹ̀kọ́ tó wúlò fún wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa kọ́ níbẹ̀.
2. Kí la lè ṣe táwọn èèyàn á fi nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa?
2 Máa Sọ̀rọ̀ Ìtùnú àti Ìrètí: Téèyàn bá kọ́kọ́ ka ìwé Náhúmù, ó lè dà bíi pé kìkì ìkéde ìdájọ́ lòdì sí Nínéfè tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ Ásíríà nìkan ló wà nínú rẹ̀. (Náh. 1:1; 3:7) Àmọ́ ṣá o, ìròyìn ayọ̀ ni ìkéde ìdájọ́ yìí jẹ́ fáwọn èèyàn Jèhófà. Náhúmù tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Olùtùnú,” mú kó dá àwọn Júù bíi tirẹ̀ lójú pé láìpẹ́ àwọn ọ̀tá àwọn kò ní sí mọ́! Náhúmù tún tẹnu mọ́ ọn pé Jèhófà jẹ́ “ibi odi agbára ní ọjọ́ wàhálà.” (Náh. 1:7) Bí àwa náà ṣe ń wàásù, ìhìn rere là ń sọ fún àwọn èèyàn, a sì ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n fi Jèhófà ṣe ibi ààbò wọn.—Náh. 1:15.
3. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Náhúmù nípa lílo àpẹẹrẹ àti àpèjúwe?
3 Máa Lo Àpẹẹrẹ àti Àpèjúwe: Jèhófà mí sí Náhúmù láti fi ìparun Nínéfè wé ti ìlú Tíbésì tó wà ní Íjíbítì (No-ámónì) tí orílẹ̀-èdè Ásíríà sọ di ahoro. (Náh. 3:8-10) Bí a ṣe ń sọ fún àwọn èèyàn pé òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí ti sún mọ́lé, ó yẹ ká tọ́ka sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì tó fi ẹ̀rí hàn pé ọ̀rọ̀ Jèhófà yóò ṣẹ láìkù síbì kan. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 632 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà tí àwọn ará Bábílónì àtàwọn ará Mídíà wá kógun ja ìlú Nínéfè, àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò mú kí Odò Tígírísì kún àkúnya, èyí sí wó apá kan lára ògiri ìlú náà tó dà bíi pé kò ṣeé dá lu tẹ́lẹ̀. Ni wọ́n bá yára ṣẹ́gun ìlú Nínéfè gẹ́lẹ́ bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀.—Náh. 1:8; 2:6.
4. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa ṣe kedere kó sì yéni tá a bá ń wàásù?
4 Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Ṣe Kedere, Kó sì Yéni: Èdè àpèjúwe tó ṣe kedere ni Náhúmù fi kọ ìwé rẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣe kedere. (Náh. 1:14; 3:1) Bákan náà, èdè tó máa tètè yé àwọn èèyàn tí à ń bá sọ̀rọ̀ ló yẹ ká máa lò. (1 Kọ́r. 14:9) Nígbà tó o bá kọ́kọ́ wàásù fún ẹnì kan, sọ ìdí tó o fi wá fún ẹni náà lọ́nà tó ṣe kedere. Máa ran ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ wọn nínú Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè túbọ̀ máa lágbára, kí wọ́n sì rí bí ohun tí wọ́n ń kọ́ ṣe kan àwọn fúnra wọn.—Róòmù 10:14.
5. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Náhúmù mú kó dá wa lójú?
5 Ìgbẹ́kẹ̀lé tí Náhúmù ní pé ọ̀rọ̀ Jèhófà yóò ṣẹ láìkùnà hàn kedere jálẹ̀ ìwé Bíbélì tá a fi orúkọ rẹ̀ pè. Bí òpin ayé Sátánì yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, à ń rí ìtùnú nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé: “Wàhálà kì yóò dìde nígbà kejì.”—Náh. 1:9.