ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “WÀÁSÙ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ, WÀ LẸ́NU RẸ̀ NÍ KÁNJÚKÁNJÚ.”—2 TÍM. 4:2.
Bí A Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tá A Gbà Gbọ́ Nípa Ọdún 1914
Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú pé kí á “wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà” ìgbàgbọ́ wa, ‘kí a sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.’ (1 Pét. 3:15) Ká sòótọ́, ó lè máà rọrùn láti ṣàlàyé àwọn òtítọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀, irú bí a ṣe mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́dún 1914. Ká lè mọ bí a ṣe lè ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́, a ti ṣe ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ alápá méjì kan tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan—Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀?” Àwọn àpilẹ̀kọ yìí wà nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tá a máa fi lọni lóṣù October àti November. Bí o ṣe ń ṣàyẹ̀wò àwọn àpilẹ̀kọ yìí, wo àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí nípa ọ̀nà tí Kọ́lá tó jẹ́ akéde nínú àpilẹ̀kọ náà gbà ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́.
Báwo ló ṣe . . .
gbóríyìn fún ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀ lọ́nà tí yóò fi nífẹ̀ẹ́ sóhun tó fẹ́ sọ?—Ìṣe 17:22.
fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn nígbà tó ń ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́?—Ìṣe 14:15.
Kí nìdí tó fi dáa bó ṣe ń . . .
ṣe àkópọ̀ ohun tó sọ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kí ó tó ṣe àwọn àlàyé míì?
dánu dúró lóòrèkóòrè tó sì ń béèrè bóyá onílé náà lóye àlàyé tó ń ṣe fún un?
ṣe àlàyé tó mọ níwọ̀n, tí kò máa da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ wuuruwu nígbà tó ń bá onílé sọ̀rọ̀?—Jòh. 16:12.
A mà dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà ‘Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá’ o, fún bó ṣe ń kọ́ wa ní ọ̀nà tá a lè gbà ṣàlàyé àwọn òtítọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ fún àwọn tí ebi òtítọ́ ń pa!—Aísá. 30:20.