“Mi Ò Kì Í Bá A Nílé!”
Ǹjẹ́ o ti sọ bẹ́ẹ̀ rí nípa ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ? Pẹ̀lú gbogbo bó o ṣe ń pa dà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ léraléra tó, kò ṣeé ṣe fún ọ láti bomi rin irúgbìn òtítọ́ tó o gbìn. (1 Kọ́r. 3:6) Nígbà mí ì, àwọn akéde tó nírìírí máa ń kọ lẹ́tà sí ẹni tí wọn kì í bá nílé tàbí kí wọ́n kọ ìwé pélébé kan sílẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà dè é. Àwọn akéde kan mọ̀ pé ó lè ṣòro láti bá ẹni tí wọ́n wàásù fún nílé nígbà mí ì, torí náà wọ́n máa ń gba nọ́ńbà fóònù ẹni náà, wọ́n á sì béèrè pé “Ṣé mo lè fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí fóònù yín?” A lè ròyìn ìpadàbẹ̀wò tá a bá pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan tàbí tá a jẹ́rìí fún un nípasẹ̀ lẹ́tà, lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà, àtẹ̀jíṣẹ́, ìwé pélébé kan tá a kọ sílẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà tàbí tá a bá pe ẹni náà lórí fóònù. Nípa báyìí, a ó mú kí ẹni tá a wàásù fún túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kódà tí kì í bá sí nílé.