ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb20 November ojú ìwé 7
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Tẹlifóònù Wàásù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Tẹlifóònù Wàásù
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjẹ́rìí Orí Tẹlifóònù Tó Ń Yọrí sí Rere
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Fífi Fóònù Wàásù Máa Ń Gbéṣẹ́ Gan-an
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Múra Ọkàn Onílé Sílẹ̀ De Ìgbà Ìpadàbẹ̀wò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • “Mi Ò Kì Í Bá A Nílé!”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
mwb20 November ojú ìwé 7
Àwòrán: Ọ̀dọ́kùnrin kan àti tọkọtaya àgbàlagbà kan ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ lórí fóònù. 1. Arákùnrin náà ń bá ọkùnrin kan sọ̀rọ̀ lórí fóònù. 2. Ibi iṣẹ́ ni ọkùnrin tí wọ́n ń bá sọ̀rọ̀ náà wà, àmọ́ ó fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ń bá a sọ.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Máa Fi Tẹlifóònù Wàásù

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Ọ̀nà pàtàkì míì tá a lè gbà “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere” ni pé ká fi tẹlifóònù wàásù. (Iṣe 20:24)a Ó máa jẹ́ ká lè wàásù fẹ́ni tá ò lè dé ọ̀dọ̀ ẹ̀.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Arákùnrin yẹn ń múra bó ṣe máa wàásù lórí fóònù, ó ń kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì àtàwọn kókó tó máa lò sílẹ̀.

    Múra sílẹ̀. Yan ọ̀rọ̀ tó máa wọ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn. Kọ àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ sílẹ̀. O tún lè kọ ọ̀rọ̀ bíi mélòó kan sílẹ̀, kó o lè kà á látorí fóònù ránṣẹ́ sẹ́ni náà tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sí nídìí fóònù rẹ̀ nígbà tó o pè. Tó o bá fẹ́ pe ẹni náà, á dáa kó o jókòó, kó o sì ṣí àwọn nǹkan tó o fẹ́ lò sílẹ̀ lórí tábìlì, irú bíi JW Library® tàbí jw.org®

  • Ọ̀dọ́kùnrin náà ń ran arákùnrin àgbàlagbà yẹn lọ́wọ́ láti wàásù fún ẹnì kan lórí fóònù.

    Fọkàn balẹ̀. Sọ̀rọ̀ bó o ṣe máa ń sọ̀rọ̀. Máa rẹ́rìn-ín músẹ́, kó o sì máa fara ṣàpèjúwe bíi pé ẹni náà ń rí ẹ. Má ṣe dánu dúró láìnídìí. Ó máa dáa kẹ́ ẹ pé méjì. Tí onílé bá béèrè ìbéèrè, tún ìbéèrè náà sọ kí ẹnì kejì lè gbọ́, kó sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè náà

  • Ọ̀dọ́kùnrin náà ń fi ìlujá fídíò kan ránṣẹ́ sí ẹnì kan látorí jw.org.

    Jẹ́ kí onílé mọ̀ pé wàá pè pa dà. Tẹ́ni náà bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, o lè fi ìbéèrè kan sílẹ̀ tí wàá dáhùn nígbà míì. O lè béèrè bóyá kó o mú ìtẹ̀jáde kan wá fún un tàbí kó o fi ìtẹ̀jáde náà tàbí fídíò kan ránṣẹ́ sí i lórí ìkànnì. Tó o bá rí i pé ó bọ́gbọ́n mu, jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ nípa Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó wà lórí ìkànnì wa tàbí àwọn nǹkan míì tó wà níbẹ̀.

a Tó bá bófin mu láti wàásù lórí tẹlifóònù ládùúgbò yín, ẹ rí i pé ẹ tẹ̀ lé òfin nípa bó ṣe yẹ kí ẹ lo ìsọfúnni àwọn ẹlòmíì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́