Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lọ sí Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Láìjáfara?
Tá a bá pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, kò burú láti bá àwọn ará wa sọ̀rọ̀ torí pé àárín wọn la wà. Àmọ́, tí a bá ti parí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ó yẹ ká tètè lọ sí ìpínlẹ̀ tá a ti máa wàásù láìjáfara. Iṣẹ́ ìwàásù wa jẹ́ kánjúkánjú. (2 Tím. 4:2) Bí a bá ṣe ń pẹ́ sí níbi tá a ti pàdé ni àkókò tí a fẹ́ lò lóde ẹ̀rí ń dín kù sí i. A máa láǹfààní láti gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ tó ń gbéni ró pẹ̀lú àwọn ará wa nígbà tí a bá jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Tá a bá ń lọ sí ìpínlẹ̀ tá a ti máa wàásù láìjáfara, ìyẹn á fi hàn pé a kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ bí a ṣe ń sìnrú fún Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀.—Róòmù 12:11.