ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/15 ojú ìwé 2
  • ‘Kí Ọ̀rọ̀ Wọ̀nyí Wà ní Ọkàn Rẹ’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Kí Ọ̀rọ̀ Wọ̀nyí Wà ní Ọkàn Rẹ’
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ìdílé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?—Apá Kejì
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ìjọsìn Ìdílé—Ǹjẹ́ O Lè Mú Kó Túbọ̀ Gbádùn Mọ́ni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ran Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa Rántí Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
km 8/15 ojú ìwé 2

‘Kí Ọ̀rọ̀ Wọ̀nyí Wà ní Ọkàn Rẹ’

Àwọn òbí dà bí olùṣọ́ àgùntàn. Torí pé àwọn ọmọ lè tètè ṣáko lọ tàbí kí wọ́n kó sínú ewu, àwọn òbí gbọ́dọ̀ bójú tó àwọn ọmọ wọn dáadáa. (Òwe 27:23) Báwo wá làwọn òbí ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn? Wọ́n gbọ́dọ̀ máa bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ kí wọ́n lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. (Òwe 20:⁠5) Bákan náà, àwọn òbí gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ wọn bí ẹní ń fi àwọn ohun èlò tí kò lè gbiná kọ́ ilé láti mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ wọn túbọ̀ lágbára sí i. (1 Kọ́r. 3:​10-15) Fídíò ‘Kí Ọ̀rọ̀ Wọ̀nyí Wà ní Ọkàn Rẹ’ jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé. Ẹ wo fídíò náà pa pọ̀ nínú ìdílé yín, kí ẹ sì jíròrò àwọn ìbéèrè yìí.

(1) Kí ló fà á tí ipò tẹ̀mí ìdílé Roman fi jó rẹ̀yìn? (2) Nígbà tí Arákùnrin Roman kọ́kọ́ gbìyànjú láti ṣe ìjọsìn ìdílé rẹ̀, kí nìdí tó fi rí rúdurùdu? (3) Ìlànà Bíbélì wo ló máa jẹ́ kí àwọn òbí ṣàṣeyọrí lórí ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́? (Diu. 6:​6, 7) (4) Kí ló lè mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tó gbámúṣé wà nínú ìdílé? (5) Kí làwọn ọmọ ń fẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn? (6) Báwo ni Arákùnrin àti Arábìnrin Barrow ṣe ní ipa rere lórí ìdílé Roman? (Òwe 27:17) (7) Kí ló yẹ kí olórí ìdílé kan kọ́kọ́ ṣe táá jẹ́ kí ìjọsìn ìdílé rẹ̀ ṣe àṣeyọrí? (8) Báwo ni Arákùnrin Roman ṣe ṣàtúnṣe sí ọ̀ràn ìdílé rẹ̀? (9) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé? (Éfé. 6:4) (10) Kí làwọn nǹkan tá a lè máa ṣe nígbà ìjọsìn ìdílé? (11) Báwo ni Arákùnrin Roman ṣe fi pẹ̀lẹ́tù bá Marcus sọ̀rọ̀ síbẹ̀ tó sojú abẹ níkòó nígbà tó ń bá a sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó máa ṣe ohun tó tọ́? (Jer. 17:9) (12) Báwo ni Arákùnrin àti Arábìnrin Roman ṣe mú kí Rebecca ronú jinlẹ̀ nígbà tí wọ́n ń ràn án lọ́wọ́ lórí àjọṣe tó ní pẹ̀lú Justin ọ̀rẹ́ rẹ̀? (Máàkù 12:30; 2 Tím. 2:22) (13) Báwo ni Arákùnrin àti Arábìnrin Roman ṣe fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú Jèhófà nígbà tí wọ́n ń ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé wọn? (Mát. 6:33) (14) Báwo ni fídíò yìí ṣe fi hàn pé ó ṣe pàtàkì kí àwọn olórí ìdílé máa pèsè fún ìdílé wọn nípa tẹ̀mí? (1 Tím. 5:8) (15) Gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, kí lo pinnu pé wàá máa ṣe?

ÀKÍYÈSÍ FÚN ÀWỌN OLÓRÍ ÌDÍLÉ: Àpéjọ àgbègbè tá a ṣe lọ́dún 2011 la ti wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ òde òní yìí. Nígbà tó o wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ yẹn, ǹjẹ́ o kíyèsí bó o ṣe lè mú kí ìjọsìn ìdílé rẹ sunwọ̀n sí i? Ní báyìí, báwo ni ìjọsìn ìdílé rẹ ṣe rí? Tó o bá ṣì rí i pé ó yẹ kó o ṣe àwọn àtúnṣe kan, jọ̀wọ́ gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe àtúnṣe tó bá yẹ kí ìdílé rẹ̀ lè jàǹfààní títí láé.​—Éfé. 5:​15-17.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́