ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb16 April ojú ìwé 3
  • Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Rere Tó Ń Gbéni Ró Tó sì Ń Fúnni Lókun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Rere Tó Ń Gbéni Ró Tó sì Ń Fúnni Lókun
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jobu Lo Ìfaradà—Àwa Pẹ̀lú Lè Ṣe Bẹ́ẹ̀!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • “Mi Ò Ní Fi Ìwà Títọ́ Mi Sílẹ̀!”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • A San Èrè fún Ìwà Títọ́ Jóòbù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Jèhófà Wò Ó Sàn
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
mwb16 April ojú ìwé 3

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 16-20

Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Rere Tó Ń Gbéni Ró Tó sì Ń Fúnni Lókun

Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹni tó ń gbani nímọ̀ràn máa gbéni ró

16:4, 5

  • Ìrònú dorí Jóòbù kodò, ó sì ní ẹ̀dùn ọkàn, torí náà ó nílò ìtùnú àti ìṣírí

  • Àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kò tù ú nínú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń dá a lẹ́bi tí wọ́n sì dá kún ìṣòro rẹ̀

Ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí Bílídádì sọ sí Jóòbù mú kí Jóòbù fi ìbínú sọ̀rọ̀

19:2, 25

  • Jóòbù bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí òun kú kí ara lè tu òun

  • Jóòbù pọkàn pọ̀ sórí ìrètí àjíǹde, ó sì fara dàá délẹ̀délẹ̀

Élífásì ń bá Jóòbù sọ̀rọ̀, Bílídádì àti Sófárì ń wo Jóòbù

ÀWỌN TÓ FẸ̀SÙN KAN JÓÒBÙ

Élífásì

Élífásì:

  • Ó ṣeé ṣe kí Élífásì jẹ́ ọmọ ìlú Témánì ní ilẹ̀ Édómù. Bíbélì pe ìlú Témánì ní ojúkò ọgbọ́n ilẹ̀ Édómù nínú Jeremáyà 49:7

  • Ó jọ pé Élífásì ló dàgbà jù, kó sì tún jẹ́ pé òun ni wọ́n bọ̀wọ̀ fún jù lọ lára àwọn “olùtùnú” náà. Ẹ̀ẹ̀mẹta ló sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tó sọ sì pọ̀ ju tàwọn méjì tó kù lọ

Àwọn ẹ̀sùn èké:

  • Ó bẹnu àtẹ́ lu ìwà títọ́ Jóòbù, ó sì tún sọ pé Ọlọ́run kò nígbàgbọ́ nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ (Jóòbù 4, 5)

  • Ó sọ pé Jóòbù ń kọjá àyè rẹ̀, pé ẹni burúkú ni àti pé kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run (Jóòbù 15)

  • Ó fẹ̀sùn kan Jóòbù pé ó jẹ́ oníwọra, pé kì í ṣe ìdájọ́ òdodo àti pé èèyàn kò wúlò fún Ọlọ́run (Jóòbù 22)

Bílídádì

Bílídádì:

  • Ó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ṣúà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀nà Odò Yúfírétì ló ń gbé

  • Òun ni ẹnì kejì tó sọ̀rọ̀. Ẹ̀ẹ̀mẹta ló sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò pọ̀. Àmọ́, ohun tó sọ burú ju ti Élífásì lọ

Àwọn ẹ̀sùn èké:

  • Ó sọ pé ikú tọ́ sí àwọn ọmọ Jóòbù torí pé wọ́n dẹ́sẹ̀, ó sì tún sọ pé Jóòbù pàápàá kò ní ẹ̀mí Ọlọ́run (Jóòbù 8)

  • Ó sọ pé ẹni burúkú ni Jóòbù (Jóòbù 18)

  • Ó sọ pé ìwà títọ́ ènìyàn kò nítumọ̀ (Jóòbù 25)

Sófárì

Sófárì:

  • Ọmọ Náámà ni, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé apá ìwọ̀-oòrùn gúúsù Arébíà ló ti wá

  • Òun ni ẹnì kẹta tó sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló sì burú jù lọ. Ẹ̀ẹ̀mejì péré ló sọ̀rọ̀

Àwọn ẹ̀sùn èké:

  • Ó sọ pé òfìfo ọ̀rọ̀ ni Jóòbù ń sọ, ó sì ní kí Jóòbù mú ìwà búburú ọwọ́ rẹ̀ kúrò (Jóòbù 11)

  • Ó sọ pé èèyàn burúkú ni Jóòbù àti pé ó fẹ́ràn láti máa dẹ́ṣẹ̀ (Jóòbù 20)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́