ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 45-51
Jèhófà Kò Ní Fi Ẹni Tó Ní Ìròbìnújẹ́ Ọkàn Sílẹ̀
Dáfídì ló kọ Sáàmù 51. Ó kọ ọ́ lẹ́yìn tí wòlíì Nátánì pe àfíyèsí rẹ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì tó dá pẹ̀lú Bátí-ṣébà. Ẹ̀rí ọkàn Dáfídì dà á láàmú, ó sì fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.—2Sa 12:1-14.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì dẹ́ṣẹ̀, síbẹ̀ àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ṣì lè dáa
Kí Dáfídì tó ronú pìwà dà tó sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ti ń dà á láàmú
Ẹ̀dùn ọkàn Dáfídì pọ̀ torí pé ó pàdánù ojú rere Ọlọ́run, èyí mú kó ronú pé òun dà bí ẹni tí wọ́n fọ́ egungun rẹ̀
Dáfídì fẹ́ kí Jèhófà dárí ji òun kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀, kó sì lè máa láyọ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀
Dáfídì fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ kí òun lè tètè máa ṣègbọràn sí i
Ó dá Dáfídì lójú pé Jèhófà máa dárí ji òun