Wọ́n ń wàásù ìhìn rere ní Gánà
Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
ILÉ ÌṢỌ́
Béèrè ìbéèrè: Àwọn kan sọ pé Bíbélì kò bágbà mu mọ́, àwọn míì sì gbà pé ó ṣì wúlò fún wa. Kí lèrò ti yín?
Ka Bíbélì: 2Ti 3:16, 17
Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí sọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì, ó sì tún sọ ohun tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ jàǹfààní nínú Bíbélì kíkà.
MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI
Béèrè ìbéèrè: Ṣé òpin ayé ti sún mọ́lé?
Òtítọ́: Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé àkókò òpin là ń gbé yìí. Ìròyìn ayọ̀ nìyẹn sì jẹ́ fún wa, torí pé ìgbà ọ̀tun máa tó wọlé dé.
ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!
Béèrè ìbéèrè: Àwọn kan ronú pé Ọlọ́run dá ayé yìí kó lè fi mọ àwọn èèyàn tó máa yege láti lọ gbé pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run, kí lèrò ti yín?
Fi ìwé lọni: Ìwé pẹlẹbẹ yìí ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Ọlọ́run dá ayé yìí káwọn èèyàn lè máa gbé inú rẹ̀ títí láé. Màá fẹ́ pa dà wá ká lè jọ sọ̀rọ̀ lórí ìbéèrè àkọ́kọ́ lójú ìwé 10, tó sọ pé: “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé yìí?”
KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ
Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.