Àwọn ará ń fi ìwé Ìròyìn Ayọ̀ lọni ní orílẹ̀-èdè Azerbaijan
Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
JÍ!
Béèrè ìbéèrè: Báwo la ṣe lè máa lo àkókò wa bó ṣe tọ́?
Ka Bíbélì: Onw 4:6
Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Jí! yìí sọ bá a ṣe lè mọ àwọn ohun tó yẹ ká fi sí ipò àkọ́kọ́.
MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI
Béèrè ìbéèrè: Kí nìdí tá a fi wà láyé?
Ka Bíbélì: Sm 37:29
Òtítọ́: Ọlọ́run dá àwa èèyàn ká lè máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé.
ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!
Béèrè ìbéèrè: Ibo lo rò pé a ti lè rí ìròyìn ayọ̀? [Jẹ́ kí onílé wo fídíò náà, Ṣé O Fẹ́ Gbọ́ Ìròyìn Ayọ̀?]
Ka Bíbélì: Ais 52:7
Fi ìwé lọni: Ìwé yìí sọ nípa “ìhìn rere ohun tí ó dára jù,” torí pé láti inú Bíbélì ni àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ti wá.
KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ
Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ