Akéde kan ń fi ìwé Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀ lọni ní orílẹ̀-èdè Jọ́jíà
Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
ILÉ ÌṢỌ́
Béèrè ìbéèrè: Ta ló fúnni lẹ́bùn tó dára jù lọ láyé àti ọ̀run?
Ka Bíbélì: Jak 1:17
Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí sọ ohun tó máa jẹ́ ká lè mọrírì ẹ̀bùn tó dára jù lọ tí Ọlọ́run fún wa.
MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI
ÌDÍLÉ RẸ LÈ JẸ́ ALÁYỌ̀
Ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀: À ń fi fídíò kékeré kan tó sọ̀rọ̀ nípa ìdílé han àwọn èèyàn. [Fi fídíò tó nasẹ̀ ìwé Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀ hàn án.]
Fi ìwé lọni: Tẹ́ ẹ bá fẹ́ ka ìwé tí fídíò yẹn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, mo lè fún yín ní ọ̀kan lọ́fẹ̀ẹ́ tàbí kí n fi bẹ́ ẹ ṣe lè wà á jáde lórí ìkànnì hàn yín.
KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ
Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.