Àwọn ará ń wàásù láti ilé dé ilé ní orílẹ̀-èdè Ítálì
Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
ILÉ ÌṢỌ́
Béèrè ìbéèrè: Ṣé Ọlọ́run fẹ́ ká máa kú?
Ka Bíbélì: Iṣi 21:4
Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìyè àti ikú.
MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI
BÁWO LA ṢE MÁA Ń ṢE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ?
Fi ìwé lọni: Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́, kí wọ́n lè mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè bíi: Kí nìdí tí ìyà fi pọ̀ láyé? Báwo ni ìdílé mi ṣe lè láyọ̀? Fídíò kékeré yìí sọ bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. [Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?.] A lè máa jíròrò láti inú ìwé yìí. [Fi ọ̀kan lára àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa hàn án, tó bá sì ṣeé ṣe, fi bá a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án.]
KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ
Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ