ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 63-66
Ọ̀run Tuntun àti Ayé Tuntun Máa Mú Ká Láyọ̀ Tó Kọ Yọyọ
Ìlérí ìmúbọ̀sípò tí Ọlọ́run ṣe nínú Aísáyà orí 65 dájú pé ó máa ṣẹ, ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ ọ́ bí ohun tó ti ṣẹlẹ̀.
Jèhófà máa dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun, àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí
Kí ni ọ̀run tuntun?
Ó jẹ́ ìjọba tuntun kan tó máa mú kí òdodo gbilẹ̀ kárí ayé
Ó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 nígbà tí Ọlọ́run gbé Kristi gorí ìtẹ́, tó sì di Ọba Ìjọba Ọlọ́run
Kí ni ayé tuntun?
Àpapọ̀ àwọn èèyàn láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè, èdè, àti ẹ̀yà tí wọ́n fayọ̀ gbà láti wà lábẹ́ ìṣàkóso ìjọba ọ̀run tuntun
Báwo ni àwọn ohun àtijọ́ kò ṣe ní wá sí ìrántí?
Kò ní sí ohun tó máa mú ká rántí àwọn nǹkan tó lè bà wá nínú jẹ́ mọ́
Àwọn olóòótọ́ èèyàn máa gbádùn ayé wọn dọ́ba, ojoojúmọ́ ni inú wọn á máa dùn