ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb17 April ojú ìwé 2
  • Fi Ọ̀yàyà Kí Wọn Káàbọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Ọ̀yàyà Kí Wọn Káàbọ̀
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Máa Jẹ́rìí Lọ́nà Tó Múná Dóko
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Ẹ Kí Àwọn Tá A Pè Káàbọ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Ẹ Fi Ọ̀yàyà Kí Wọn Káàbọ̀!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Báwo La Ṣe Lè Ran Àwọn Tó Bá Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Lọ́wọ́?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
mwb17 April ojú ìwé 2

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Fi Ọ̀yàyà Kí Wọn Káàbọ̀

Àwọn wo la fẹ́ fi ọ̀yàyà kí káàbọ̀? Ẹnikẹ́ni tó bá wá sí àwọn ìpàdé wa, ì báà jẹ́ àwọn tó ṣẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wá tàbí àwọn tá a ti jọ wà tipẹ́. (Ro 15:7; Heb 13:2) Ó lè jẹ́ àwọn ará wa tó wá láti orílẹ̀-èdè míì tàbí àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ tó jẹ́ pé fún ọ̀pọ̀ ọdún ni wọn ò ti wá sípàdé mọ́. Tó bá jẹ́ pé àwa la wà ní èyíkéyìí lára àwọn ipò tá a sọ yìí, ṣé a ò ní fẹ́ kí wọ́n fi ọ̀yàyà kí wa káàbọ̀? (Mt 7:12) Torí náà, á dáa tá a bá lè gbìyànjú láti máa kí àwọn tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti nígbà tí ìpàdé bá parí. Èyí á mú kí ara tu gbogbo wa, ìfẹ́ á máa gbilẹ̀ láàárín wa, a ó sì máa tipa bẹ́ẹ̀ bọlá fún Jèhófà. (Mt 5:16) Òótọ́ ni pé ó lè má ṣeé ṣe fún wa láti kí gbogbo àwọn tó wà nípàdé lọ́kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, tí kálukú wa bá ń ṣe ipa tirẹ̀, ara máa tu gbogbo wa.a

Kì í ṣe ìgbà tá a bá ń ṣe àwọn àkànṣe ìpàdé bí Ìrántí Ikú Kristi nìkan ló yẹ ká máa fọ̀yàyà kí àwọn èèyàn, ìgbà gbogbo ló yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Tí àwọn ẹni tuntun bá rí i pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa lóòótọ́, èyí á mú kí wọ́n máa yin Ọlọ́run, wọ́n sì lè wá dara pọ̀ mọ́ wa nínú ìjọsìn tòótọ́.​—Jo 13:35.

a Tí àwọn tá a ti yọ lẹ́gbẹ́ àtàwọn tó mú ara wọn kúrò lẹ́gbẹ́ bá wá sípàdé, ká má gbàgbé ìlànà Bíbélì tó sọ pé ká fi ààlà sí àjọṣe wa pẹ̀lú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀.​—1Kọ 5:11; 2Jo 10.

Arákùnrin kan ń kí àwọn ẹni tuntun káàbọ̀ sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba

ÀWỌN ÀBÁ NÍPA BÁ A ṢE LÈ RAN ÀWỌN ẸNI TUNTUN LỌ́WỌ́

  • Sọ orúkọ rẹ, kó o sì béèrè orúkọ wọn

  • Ní kí wọ́n wá jókòó tì ẹ́

  • Ẹ jọ lo Bíbélì àti ìwé orin rẹ

  • Tí ìpàdé bá ti parí, ẹ jọ sọ̀rọ̀, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n bá ní

  • Tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, béèrè bóyá wọ́n á fẹ́ kó o wá máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́