MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jèhófà Kì Í Gbàgbé Ìfẹ́ Tá A Fi Hàn
WO FÍDÍÒ NÁÀ, JÈHÓFÀ KÌ Í GBÀGBÉ ÌFẸ́ TÁ A FI HÀN, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Ìṣòro wo làwọn àgbàlagbà máa ń ní?
Ìwà rere wo làwọn àgbàlagbà máa ń ní?
Ẹ̀yin àgbàlagbà, ìṣírí wo lẹ rí nínú Léfítíkù 19:32 àti Òwe 16:31?
Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ tó ti dàgbà, àmọ́ tí wọn ò lè ṣe tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn?
Kí ni Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe, kódà bá a bá tiẹ̀ ti dàgbà?
Báwo làwọn àgbàlagbà ṣe lè fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí?
Báwo ni arákùnrin tàbí arábìnrin àgbàlagbà kan ṣe fún ẹ níṣìírí lẹ́nu àìpẹ́ yìí?