ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ỌBADÁYÀ 1–JÓNÀ 4
Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Àwọn Àṣìṣe Rẹ
Ìwé Jónà fi hàn pé Jèhófà kì í pa wá tì nígbà tá a bá ṣe àṣìṣe. Àmọ́, ó fẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn àṣìṣe wa ká sì ṣàtúnṣe tó yẹ.
Àṣìṣe wo ni Jónà ṣe nígbà tí Jèhófà rán an níṣẹ́?
Kí ni Jónà gbàdúrà fún, báwo sì ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà rẹ̀?
Báwo ni Jónà ṣe fi hàn pé ó kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn àṣìṣe rẹ̀?