Àwọn ará kan ń wàásù ní ọjà kan lórílẹ̀-èdè Sierra Leone
Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
JÍ!
Béèrè ìbéèrè: Kí nìdí tó fi dà bíi pé ayé yìí ti bà jẹ́ kọjá àtúnṣe?
Ka Bíbélì: Jer 10:23
Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gbà pé nǹkan ṣì ńbọ̀ wá dáa.
JÍ!
Béèrè ìbéèrè: Ṣé Ọlọ́run ní orúkọ?
Ka Bíbélì: Sm 83:18
Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí àti ìdí tó fi yẹ ká máa lo orúkọ náà. [Ṣí i sí àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì—Orúkọ Ọlọ́run.”]
MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI
Béèrè ìbéèrè: Ǹjẹ́ ìgbà kan tiẹ̀ lè wà tí ikú tó jẹ́ ọ̀tá àwa èèyàn ò ní sí mọ́?
Ka Bíbélì: 1Kọ 15:26
Òtítọ́: Jèhófà máa mú ikú kúrò pátápátá.
KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ
Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ