MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Kí Ni Ìfẹ́ Tòótọ́?
Jèhófà ṣètò ìgbéyàwó lọ́nà tí ọkùnrin kan àti obìnrin kan á fi wà pa pọ̀ títí láé. (Jẹ 2:22-24) Ohun kan ṣoṣo tó lè mú kí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀ ni tí ọ̀kan nínú wọn bá ṣèṣekúṣe pẹ̀lú ẹlòmíì. (Mal 2:16; Mt 19:9) Torí pé Jèhófà fẹ́ kí ìgbéyàwó láyọ̀, ó fún àwa Kristẹni ní àwọn ìlànà Bíbélì tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fi ọgbọ́n yan ẹni tí a máa fẹ́, ká sì ní ìgbéyàwó aláyọ̀.—Onw 5:4-6.
WO FÍDÍÒ KÍ NI ÌFẸ́ TÒÓTỌ́?, LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n àti onífẹ̀ẹ́ ni Frank àti Bonnie fun Liz ọmọbìnrin wọn?
Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti ronú pé o lè yí ìwà àfẹ́sọ́nà rẹ pa dà?
Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n wo ni Arákùnrin Paul àti Arábìnrin Priscilla fún Liz?
Kí nìdí tí Zach àti Megan fi ń ní ìṣòro nínú ìgbéyàwó wọn?
Àfojúsùn tẹ̀mí wo ni John àti Liz jọ ní?
Kí nìdí tó fi yẹ kó o mọ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà” ẹni tó o fẹ́ fẹ́ kó o tó jẹ́jẹ̀ẹ́ ìgbéyàwó pẹ̀lú onítọ̀hún? (1Pe 3:4)
Kí ni ìfẹ́ tòótọ́? (1Ko 13:4-8)