ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb18 February ojú ìwé 5
  • Jésù Ń Tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Ń Tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jésù Ń tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • “Ní Ti Tòótọ́, Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ Àti Olóye?”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ó Fi Ìwọ̀nba Búrẹ́dì àti Ẹja Bọ́ Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Èèyàn
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • “Ẹ Máa Rántí Àwọn Tó Ń Mú Ipò Iwájú Láàárín Yín”
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
mwb18 February ojú ìwé 5
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 14-15

Jésù Ń Tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn

Nígbà tó kú díẹ̀ kí ìrékọjá wáyé ní ọdún 32 Sànmánì Kristẹni, Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu kan, ó sì wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.

Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu yìí, Jésù fi ìpìlẹ̀ ohun pàtàkì kan lélẹ̀ tó ṣì ń lò títí di àkókò yìí.

14:16-21

  • Jésù ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn bó tiẹ̀ jẹ́ pé búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì ni wọ́n ní

  • Jésù mú búrẹ́dì àti ẹja náà, lẹ́yìn tó gbàdúrà sí i, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pín in fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn náà sì ń pín in fún àwọn èèyàn náà

  • Iṣẹ́ ìyanu ló jẹ́ torí pé oúnjẹ náà tó gbogbo èèyàn láti jẹ. Jésù tipasẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kéréje bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún

    Jésù pín búrẹ́dì fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀; ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́
  • Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, òun máa yan àwọn kan táá máa pèsè ‘oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.’​—⁠Mt 24:⁠45

  • Ní ọdún 1919, Jésù yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” ìyẹn àwùjọ èèyàn kéréje tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró láti máa bójú tó àwọn “ará ilé rẹ̀,” ìyẹn àwọn tí ẹrú yẹn ń fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́

  • Nípasẹ̀ àwùjọ àwọn ẹni àmì òróró kéréje yìí, Jésù ń tẹ̀ lé ìpìlẹ̀ tó fi lélẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní

Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé mo mọ àwọn tí Jésù ń lò láti fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ àwọn èèyàn, báwo ni mo sì ṣe lè fi hàn pé mo bọ̀wọ̀ fún wọn?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́