ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 8-9
Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Di Ọmọlẹ́yìn?
Tí àgbẹ̀ tó ń kọ ebè kò bá fẹ́ kí ebè náà wọ́, kò ní jẹ́ kí àwọn ohun tó ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn pín ọkàn rẹ̀ níyà. Bákan náà, Kristẹni kan kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn nǹkan tó ti fi sílẹ̀ nínú ayé pín ọkàn rẹ̀ níyà.—Flp 3:13.
Tá a bá wà nínú ìṣòro, ó rọrùn láti máa ronú pé àwọn àsìkò kan wà tí ‘nǹkan dáa fún wa jù báyìí lọ,’ bóyá ká tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Tá a bá nírú èrò yìí, ó lè mú ká máa ronú pé àwọn ìṣòro tá a ní nígbà yẹn kò tó nǹkan àti pé a láyọ̀ nígbà yẹn ju báyìí lọ. Ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe nìyẹn nígbà tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì. (Nu 11:5, 6) Tá a bá ń ní irú èrò yìí, ó lè mú kó máa wù wá láti pa dà sí irú ìgbésí ayé tá a gbé nígbà yẹn. Torí náà, ohun tó dáa jù ni pé ká máa ronú lórí àwọn ìbùkún tá a ní báyìí àtàwọn ohun rere tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú!—2Kọ 4:16-18.