ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KỌ́RÍŃTÌ 7-10
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìrànwọ́ Tá À Ń Ṣe
Ọ̀nà méjì ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwa Kristẹni pín sí, àkọ́kọ́ ni “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìpadàrẹ́” tàbí iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, ìkejì ni “iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìrànwọ́” tá à ń ṣe fún àwọn ará wa. (2Kọ 5:18-20; 8:4) Torí náà, tá a bá ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ará wa tó wà nínú ìṣòro, ara iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ là ń ṣe. Táwa náà bá ń lọ́wọ́ nínú apá iṣẹ́ ìsìn yìí, ṣe là ń
pèsè fún àwọn ará wa tó wà nínú àìní.—2Kọ 9:12a
ran àwọn tí àjálù dé bá lọ́wọ́, kí wọ́n lè máa ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ti máa ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà tẹ́lẹ̀, irú bí iṣẹ́ ìwàásù, èyí tó máa fi hàn pé wọ́n mọrírì ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wọn.—2Kọ 9:12b
fi ògo fún Jèhófà. (2Kọ 9:13) Ètò ìrànwọ́ tá à ń ṣe máa ń jẹ́rìí fún gbogbo èèyàn, títí kan àwọn tí kò fẹ́ràn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà