ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 10-11
Àpèjúwe Ará Samáríà
Jésù sọ àpèjúwe yìí nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè tẹ́nì kan bí i pé, “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” (Lk 10:25-29) Jésù mọ̀ pé tó bá yá “onírúurú ènìyàn gbogbo” ló máa wà nínú ìjọ Kristẹni, tó fi mọ́ àwọn ará Samáríà àtàwọn Kèfèrí. (Jo 12:32) Àpèjúwe yìí kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọ́n ní láti sa gbogbo ipá wọn láti fìfẹ́ hàn sí àwọn èèyàn, títí kan àwọn tó ṣeé ṣe kó yàtọ̀ sí wọn pàápàá.
BI ARA RẸ PÉ:
‘Ojú wo ni mo fi ń wo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tèmi?’
‘Ṣé àwọn tí ọ̀rọ̀ wa jọra nìkan ni mo máa ń bá da nǹkan pọ̀?’
‘Ṣé mo lè gbòòrò síwájú nípa títúbọ̀ mọ àwọn ará tí ọ̀nà tí wọ́n gbà tọ́ wọn dàgbà yàtọ̀ sí tèmi?’ (2Kọ 6:13)
Mo fẹ́ pe
ká jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí
kó wá bá wa jẹun
kó wá bá wa ṣe Ìjọsìn Ìdílé