ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÚÙKÙ 14-16
Àpèjúwe Ọmọ Tó Sọ Nù
Díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ látinú àpèjúwe yìí.
Ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ tá a bá dúró síbi ààbò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run, níbi tí Baba wa ọ̀run ti ń bójú tó wa
Tá a bá yà kúrò ní ọ̀nà Ọlọ́run, ó yẹ ká fìrẹ̀lẹ̀ pa dà, ká sì ní ìdánilójú pé Jèhófà máa dárí jì wá
A gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, ká máa fi tinútinú gba àwọn tó ronú pìwà dà, tí wọ́n sì pa dà wá sínú ìjọ