ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 4-5
Wọ́n Ń Fi Àìṣojo Sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Kí ló mú kí àwọn àpọ́sítélì di olùkọ́? Kí ló mú kí wọ́n lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú àti ìgboyà? “Wọ́n ti máa ń wà pẹ̀lú Jésù,” Olùkọ́ Ńlá náà, wọ́n sì ti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. (Iṣe 4:13) Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára Jésù tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti di olùkọ́ni tó dáńgájíá?