MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ni Kó O Máa Lé
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Olùkọ́ Atóbilọ́lá ni Jèhófà, ó ń fún wa ní ẹ̀kọ́ tó dáa jù lọ. Ó ń kọ́ wa bá a ṣe lè gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀, ó sì ń múra wa sílẹ̀ fún ọjọ́ iwájú aláyọ̀ tá à ń retí, gbogbo èyí ló ń ṣe fún wa lọ́fẹ̀ẹ́! (Ais 11:6-9; 30:20, 21; Ifi 22:17) Jèhófà tún ń lo ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá yìí láti múra wa sílẹ̀ fún iṣẹ́ tó ń gbẹ̀mí là tá à ń ṣe lónìí.—2Kọ 3:5.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Sapá láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti oníwà pẹ̀lẹ́.—Sm 25:8, 9
Máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ báyìí, irú bí iṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́, ní ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀
Ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí.—Flp 3:13
Yááfì àwọn nǹkan, kó o bàa lè tóótun láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i.—Flp 3:8
WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ̀KỌ́ JÈHÓFÀ SỌ WÁ DI ỌLỌ́RỌ̀ NÍPA TẸ̀MÍ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Irú àwọn ìṣòro wo ni àwọn akéde kan ti borí kí wọ́n lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run?
Irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo ni àwọn tó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run máa ń rí gbà?
Nígbà tí àwọn tó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí dé ibi iṣẹ́ àyànfúnni wọn, báwo ni àwọn ará ìjọ ibẹ̀ ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́?
Kí ni ẹni tó bá fẹ́ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run gbọ́dọ̀ dójú ìlà ẹ̀? (kr 189)
Èwo nínú àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ míì tí ètò Ọlọ́run pèsè lo tún lè fi ṣe àfojúsùn rẹ?
Àwọn ìbùkún wo lo máa rí tó o bá fi ṣe àfojúsùn rẹ láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run?