ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb20 December ojú ìwé 7
  • Ṣé Wàá Fẹ́ Lọ Sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Wàá Fẹ́ Lọ Sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere?
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí A Ṣe Ń Dá Àwọn Òjíṣẹ́ Ìjọba Náà Lẹ́kọ̀ọ́
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Sapá Kó O Lè Lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Àwọn Míṣọ́nnárì Ń Wàásù ní “Ibi Tó Jìnnà Jù Lọ ní Ayé”
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • Ilé Ẹ̀kọ́ Kan Táwọn Tó Jáde Níbẹ̀ Ń Ṣe Àwọn Èèyàn Láǹfààní Jákèjádò Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
mwb20 December ojú ìwé 7
Àwọn tó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣé Wàá Fẹ́ Lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere?

Ṣé aṣáájú-ọ̀nà ni ẹ́, ṣé ọjọ́ orí ẹ̀ ṣì wà láàárín ọdún mẹ́tàlélógún [23] sí márùndínláàádọ́rin [65]? Ṣé o ní ìlera tó dáa, ṣé wàá sì lè lọ sìn níbikíbi tá a bá ti nílò àwọn oníwàásù sí i? Tí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sáwọn ìbéèrè yìí, ṣé wàá fẹ́ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere? Látìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tọkọtaya, arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọn ò tíì ṣègbéyàwó ló ti lọ síbẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, a túbọ̀ nílò àwọn arákùnrin tí ò tíì ṣègbéyàwó nílé ẹ̀kọ́ yìí. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó wù ẹ́ láti túbọ̀ máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kó o sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọmọ rẹ̀. (Sm 40:8; Mt 20:28; Heb 10:7) Lẹ́yìn náà, ronú nípa bó o ṣe lè dín ojúṣe rẹ tàbí iṣẹ́ tó ò ń ṣe kù kó o lè tóótun láti lọ sílé ẹ̀kọ́ yìí.

Àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wo làwọn tó lọ sílé ẹ̀kọ́ yìí máa ń ní? Àwọn kan lára wọn ti lọ sìn níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwọn, àwọn míì sì tí kópa níbi àkànṣe ìwàásù láwọn ìlú térò pọ̀ sí. Àwọn kan ti di alábòójútó àyíká, adelé alábòójútó àyíká tàbí míṣọ́nnárì. Bó o ṣe ń ronú láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ṣe lò ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wòlíì Àìsáyà tó sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi!”​—Ais 6:8.

WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN MÍṢỌ́NNÁRÌ Ń ṢÍṢẸ KÁRA LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Àwọn Míṣọ́nárì Ń Ṣíṣẹ Kára Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù.’ Tọkọtaya tó jẹ́ míṣọ́nnárì ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù.

    Báwo ni wọ́n ṣe ń yan àwọn míṣọ́nnárì?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Àwọn Míṣọ́nárì Ń Ṣíṣẹ Kára Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù.’ Arábìnrin kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì àti arábìnrin mí ì jọ ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú obìnrin kan.

    Iṣẹ́ wo làwọn míṣọ́nnárì ń ṣe?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Àwọn Míṣọ́nárì Ń Ṣíṣẹ Kára Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù.’ Arákùnrin míṣọ́nnárì kan tó ń sìn níjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè àwọn adití ń fún arákùnrin mí ì níṣìírí pé kó buwọ́ lù fọ́ọ̀mù iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.

    Ìbùkún wo làwọn míṣọ́nnárì máa ń rí?

Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere, lọ sórí ìkànnì jw.org, lábẹ́ “Fídíò” tó wà ní abala Ohun Tá A Ní, lọ sí IṢẸ́ WA > ÀWỌN ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÈTÒ ỌLỌ́RUN ÀTI ÌDÁLẸ́KỌ̀Ọ́. Wo àwọn fídíò yìí Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run ní Àárín Gbùngbùn Áfíríkà, Ẹ̀kọ́ Jèhófà Sọ Wá Di Ọlọ́rọ̀ Nípa Tẹ̀mí, àti Ayẹyẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́yege Kíláàsì Àkọ́kọ́ Nílé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́