MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bí Gbogbo Wa Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa
Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa kì í ṣe ilé kan lásán; ibi tá a yà sí mímọ́ fún Jèhófà tá a sì ti ń jọ́sìn rẹ̀ ni. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè máa bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba wa?
WO FÍDÍÒ NÁÀ BÁ A ṢE LÈ MÁA BÓJÚ TÓ ÀWỌN IBI ÌJỌSÌN WA, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí la máa ń ṣe ní ibi tá a ti máa ń ṣe ìpàdé?
Kí nìdí tó fi yẹ kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní, ká sì máa ṣàtúnṣe àwọn nǹkan tó bà jẹ́?
Àǹfààní wo lo rí nígbà tó o lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ àbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba?
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣe nǹkan tó máa ṣe wá léṣe, àpẹẹrẹ wo lo rí nínú fídíò náà?
Báwo la ṣe lè fi àwọn ọrẹ wa bọlá fún Jèhófà?
BÁWO NI MO ṢE FẸ́ TI IṢẸ́ YÌÍ LẸ́YÌN?