MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bá A Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa
Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa kì í ṣe ilé kan lásán; ibi tá a yà sí mímọ́ fún Jèhófà tá a sì ti ń jọ́sìn rẹ̀ ni. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè máa bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba wa? Ẹ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá wo fídíò náà Bá A Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa.
Àwọn nǹkan wo la máa ń ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?
Kí nìdí tó fi yẹ kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní, ká sì máa tún àwọn ohun tó bà jẹ́ ṣe?
Ta ló máa ń bójú tó àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba?
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ọwọ́ pàtàkì mú ọ̀ràn ààbò, àpẹẹrẹ wo lo rí nínú fídíò náà?
Báwo la ṣe lè fi àwọn ọrẹ wa bọlá fún Jèhófà?