ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÉFÉSÙ 1-3
Iṣẹ́ Àbójútó Jèhófà àti Ohun Tó Wà Fún
Jèhófà ṣètò iṣẹ́ yìí láti mú kí gbogbo ẹ̀dá rẹ̀ olóye wà ní ìṣọ̀kan.
Ọlọ́run múra ìjọ àwọn ẹni àmì òróró sílẹ̀ láti lọ gbé lọ́run, wọ́n sì máa wà lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi tí Ọlọ́run yàn ṣe Orí wọn
Ọlọ́run ń múra àwọn tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé sílẹ̀, lábẹ́ Ìjọba Mèsáyà
Àwọn ọ̀nà wo ni mo lè gbà pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ètò Jèhófà?