MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jẹ́ Kí Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Rẹ Túbọ̀ Máa Mérè Wá
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Ìdákẹ́kọ̀ọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa jẹ́ ká “lóye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” òtítọ́ jẹ́. (Ef 3:18) Ó tún máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ aláìlábàwọ́n àti aláìlẹ́bi nínú ayé burúkú yìí, ó sì máa ràn wá lọ́wọ́ láti “di ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin.” (Flp 2:15, 16) Àwa fúnra wa la máa yan ìtẹ̀jáde tá a fẹ́ lò nígbà tá a bá fẹ́ ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí la lè ṣe láti jàǹfààní ní kíkún bá a ṣe ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀?
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
O lè fàlà sí àwọn ẹsẹ Bíbélì, kó o sì kọ àlàyé sínú Bíbélì tó o fi ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́, ó tiẹ̀ lè lo Bíbélì tó wà lórí ẹ̀rọ
Bó o ṣe ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bi ara rẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ta ni? Kí ni? Ìgbà wo? Ibo? Kí nìdí? Báwo?’
Ṣe ìwádìí. Tó o bá fẹ́ ṣèwádìí, o lè ṣèwádìí lórí ẹsẹ Bíbélì tàbí àkòrí ọ̀rọ̀ kan
Ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó o kà, kó o lè mọ bó o ṣe lè fi wọ́n sílò
Fi ohun tó ò ń kọ́ sílò lójoojúmọ́ ayé rẹ.—Lk 6:47, 48
WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ DI “Ọ̀RỌ̀ ÌYÈ MÚ ṢINṢIN”—Ẹ MÁA ṢE ÌDÁKẸ́KỌ̀Ọ́ TÓ JÍIRE, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí ni àwọn kan sọ pé a lè fi ìdákẹ́kọ̀ọ́ wé?
Kí nìdí tó fi yẹ ká gbàdúrà ní gbogbo ìgbà tá a bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́?
Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye àwọn ẹsẹ Bíbélì dáadáa?
Irú àwọn àmì wo la lè fi sínú Bíbélì tá a fi ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́?
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò nígbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
Kí ló yẹ ká ṣe sí ohun tá à ń kọ́?
“Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mò ń ronú lé e lórí.”—Sm 119:97