MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Rí Kọ́ Lára Wọn?
Ṣé o ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni àbí alàgbà? O lè ní àwọn ẹ̀bùn àbínibí kan tàbí kó o mọ àwọn nǹkan kan táwọn míì ò mọ̀, o sì lè ti lọ sílé ìwé ju àwọn míì tá a yàn sípò nínú ìjọ yín. Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè rí kọ́ lára àwọn arákùnrin yìí àtàwọn míì tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ṣùgbọ́n tí wọn kì í ṣe alàgbà mọ́, bóyá torí ará tó ti di ara àgbà, àìlera tàbí àwọn ojúṣe míì nínú ìdílé.
WO FÍDÍÒ NÁÀ BỌ̀WỌ̀ FÚN ÀWỌN ỌKÙNRIN ONÍRÌÍRÍ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
1. Báwo ni Arákùnrin Richards ṣe fi hàn pé òun bọ̀wọ̀ fún Arákùnrin Bello?
2. Àṣìṣe wo ni Ben ṣe, kí sì nìdí?
3. Ẹ̀kọ́ wo ni Ben rí kọ́ lára àpẹẹrẹ Èlíṣà?
4. Bóyá arákùnrin ni ẹ́ tàbí arábìnrin, báwo lo ṣe lè fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún àwọn ará tó nírìírí, kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn?