MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ẹ Máa Ronú Lórí Àwọn Nǹkan Yìí”
Àwọn nǹkan wo nìyẹn? Fílípì 4:8 sọ pé ká máa ronú lórí ohun tó jẹ́ òótọ́, tó ṣe pàtàkì, tó jẹ́ òdodo, tó jẹ́ mímọ́, tó yẹ ní fífẹ́, tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, tó dára, tó sì yẹ fún ìyìn. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì nìkan ni Kristẹni kan á máa rò ṣáá. Síbẹ̀, ohun tó máa múnú Jèhófà dùn ló yẹ ká máa rò. Kò yẹ ká máa ro ohun táá mú kó ṣòro fún wa láti jẹ́ olóòótọ́ sí i.—Sm 19:14.
Kò rọrùn láti gbé èròkerò kúrò lọ́kàn. Bá a ṣe ń wọ̀yá ìjà pẹ̀lú àìpé ara wa, bẹ́ẹ̀ la tún gbọ́dọ̀ wọ̀yá ìjà pẹ̀lú Sátánì tó jẹ́ “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2Kọ 4:4) Torí pé Sátánì ló ń darí ayé, èyí tó pọ̀ jù lára ohun tó ń jáde nínú tẹlifíṣọ̀n, rédíò, Íńtánẹ́ẹ̀tì àtàwọn ìwé ìròyìn ló burú jáì. Torí náà, ó yẹ ká ṣọ́ ohun tá à ń wò, tá à ń gbọ́, tá a sì ń kà. Tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan yìí lè mú ká máa ro èròkerò, ìyẹn sì lè mú ká hùwàkiwà.—Jem 1:14, 15.
JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ WO FÍDÍÒ NÁÀ YẸRA FÚN OHUN TÓ LÈ BA ÌDÚRÓṢINṢIN RẸ JẸ́—ERÉ ÌNÀJÚ TÍ KÒ BÓJÚ MU, LẸ́YÌN NÁÀ, Ẹ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí ni arákùnrin yìí ń wò lórí fóònù ẹ̀, àkóbá wo nìyẹn sì ṣe fún un?
Báwo ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Gálátíà 6:7, 8 àti Sáàmù 119:37 ṣe ràn án lọ́wọ́?