ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb19 December ojú ìwé 7
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Máa Yíwọ́ Pa Dà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Máa Yíwọ́ Pa Dà
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mímúra Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Ìròyìn Sílẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Mímú Ọ̀rọ̀ Rẹ Bá Ipò Wọn Mu
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ronú Jinlẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Máa Fi Ìlànà Pàtàkì Náà Sílò Lóde Ẹ̀rí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
mwb19 December ojú ìwé 7
Àwọn arábìnrin méjì ń lo fóònù láti wàásù fún ọkùnrin kan tó ń bójú tó agbo ẹran.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Máa Yíwọ́ Pa Dà

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn ń ké sí onírúurú èèyàn níbi gbogbo pé kí wọ́n wá “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ifi 22:17) Omi yìí dúró fún gbogbo ohun tí Jèhófà ti pèsè káwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Àmọ́, onírúurú èèyàn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀, tí wọ́n sì ń ṣe onírúurú ẹ̀sìn là ń wàásù fún. Torí náà, ká tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ wàásù “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” náà fún wọn lọ́nà tó máa wọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lọ́kàn.​—Ifi 14:6.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Yan kókó kan àti ẹsẹ Bíbélì tó o mọ̀ pé á wọ àwọn èèyàn lọ́kàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. O lè lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tàbí kókó míì tó o ti lò rí, tó sì gbéṣẹ́ gan-an. Àkòrí ọ̀rọ̀ tàbí ẹsẹ Bíbélì wo làwọn èèyàn máa ń nífẹ̀ẹ́ sí? Ṣé ìròyìn kan wà tó ń jà ràn-ìn lọ́wọ́? Irú ọ̀rọ̀ wo ni ọkùnrin máa nífẹ̀ẹ́ sí, èwo sì ni obìnrin máa nífẹ̀ẹ́ sí?

  • Kí àwọn tó o bá rí dáadáa bí wọ́n ṣe máa ń kí ara wọn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín.​—2Kọ 6:3, 4

  • Mọ àwọn ìwé àti fídíò tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ní àmọ̀dunjú, kó o lè mọ èyí tó o máa lò fẹ́ni tó bá fìfẹ́ hàn

  • Wa àwọn ìwé àti fídíò jáde ní onírúurú èdè táwọn èèyàn ń sọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín

  • O lè yí kókó ọ̀rọ̀ rẹ pa dà kó lè bá ipò onílé mu. (1Kọ 9:19-23) Bí àpẹẹrẹ, kí lo máa sọ tó o bá rí i pé onílé náà ń ṣọ̀fọ̀ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kú?

WO FÍDÍÒ NÁÀ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kókó wo ni akéde náà kọ́kọ́ ń bá onílé rẹ̀ sọ?

  • Kí ló ṣẹlẹ̀ sí onílé náà?

  • Ẹsẹ Bíbélì wo ló bá ipò onílé yẹn mu jù lọ, kí sì nìdí?

  • Báwo lo ṣe máa ń yíwọ́ pa dà kí ọ̀rọ̀ ẹ lè dọ́kàn àwọn tó ò ń wàásù fún?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́