ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 12-14
Májẹ̀mú Kan Tó Kàn Ẹ́
Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ọlọ́run máa gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run
Májẹ̀mú yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́dún 1943 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí Ábúráhámù sọdá Odò Yúfírétì bó ṣe ń lọ sílẹ̀ Kénáánì
Májẹ̀mú yìí á ṣì máa bá a lọ títí Ìjọba Mèsáyà fi máa pa gbogbo ọ̀tá Ọlọ́run run, táá sì mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún gbogbo ìdílé tó wà láyé
Jèhófà bù kún Ábúráhámù nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ tó lágbára. Táwa náà bá nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Jèhófà, àwọn ìbùkún wo la máa gbádùn nípasẹ̀ Májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ábúráhámù dá?