MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Kí Ló Lè Rí Kọ́ Nínú Àwọn Orin Wa Míì?
Èwo nínú àwọn orin wa míì lo fẹ́ràn jù? Kí nìdí tó o fi fẹ́ràn ẹ̀? Ṣé torí pé fídíò orin yẹn sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ ni? Ipò yòówù ká wà, kò sẹ́ni táwọn orin yìí ò kàn torí pé onírúurú orin aládùn tí àkòrí wọn yàtọ̀ síra ló ti wà. Àmọ́ ká fi sọ́kàn pé, kì í ṣe ìgbádùn nìkan làwọn orin yìí wà fún, wọ́n tún ń kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì.
Bí àpẹẹrẹ, àwọn orin kan sọ nípa ẹ̀mí aájò àlejò, àwọn míì dá lórí ìṣọ̀kan, ìgboyà, ìfẹ́, ìgbàgbọ́ àti béèyàn ṣe lè ní ọ̀rẹ́ tòótọ́. Àwọn orin míì tún wà tó dá lórí báwọn tó ti ṣáko lọ ṣe lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, bá a ṣe lè máa dárí jini, bá a ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ àti bá a ṣe lè ní àfojúsùn tẹ̀mí. Kódà, orin kan tiẹ̀ sọ nípa bó ṣe yẹ ká máa lo fóònù. Àwọn ẹ̀kọ́ míì wo lo ti kọ́ látinú àwọn orin yìí?
WO FÍDÍÒ ORIN NÁÀ Ó TI FẸ́RẸ̀Ẹ́ DÉ TÁN, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Ìlérí ọjọ́ iwájú wo làwọn tọkọtaya àgbàlagbà yìí ń fojú sọ́nà fún?—Jẹ 12:3
Báwo la ṣe lè túbọ̀ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà lágbára láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ?
Ohun ayọ̀ wo ló máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ sáwọn èèyàn wa tó ti kú?
Báwo làwọn ìlérí Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro tá à ń kojú lónìí?—Ro 8:25