ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 8-9
Fáráò Agbéraga Ò Mọ̀ Pé Ohun Tí Jèhófà Fẹ́ Ni Òun Ń Ṣe
Àwọn ọba ilẹ̀ Íjíbítì máa ń ka ara wọn sí ọlọ́run. Èyí ló mú kí Fáráò máa gbéra ga, kò sì tẹ́tí sí Mósè àti Áárónì títí kan àwọn àlùfáà onídán rẹ̀.
Ṣé o máa ń fetí sí àbá àwọn míì? Ṣé o máa ń mọyì ìbáwí tẹ́nì kan bá fún ẹ? Ṣé o kì í ronú pé èrò tìẹ nìkan ló tọ̀nà? Ká rántí pé “ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun.” (Owe 16:18) Ìyẹn jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká yẹra fún ẹ̀mí ìgbéraga!