ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 12
Ohun Tí Ìrékọjá Túmọ̀ sí fún Àwa Kristẹni
Káwọn ọmọ Ísírẹ́lì má bàa fara gbá ìyọnu kẹwàá, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni pàtó kan. (Ẹk 12:28) Ní alẹ́ Nísàn 14, Mósè fún ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ìtọ́ni pé kí wọ́n wà nínú ilé wọn. Kí wọ́n pa ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan tàbí ewúrẹ́ tára ẹ̀ dá ṣáṣá, kí wọ́n sì wọ́n ẹ̀jẹ́ rẹ̀ sára àwọn òpó ilẹ̀kùn àti apá òkè ẹnu ọ̀nà. Lẹ́yìn náà, kí wọ́n yan gbogbo ẹran náà nínú iná, kí wọ́n sì yára jẹ ẹ́. Ẹnì kankan ò gbọ́dọ̀ jáde nínú ilé rẹ̀ títí ilẹ̀ fi máa mọ́.—Ẹk 12:9-11, 22.
Àwọn ọ̀nà pàtó wo ni ìgbọ́ràn gbà ń dáàbò bò wá lónìí?