Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìrékọjá kò ṣàpẹẹrẹ Ìrántí Ikú Kristi, síbẹ̀ apá kan wà nínú rẹ̀ tó ní ìtumọ̀ pàtàkì fún wa. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe Jésù ní “ìrékọjá wa.” (1Kọ 5:7) Bí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn tí wọ́n fi sí àtẹ́rígbà ilẹ̀kùn ṣe gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀jẹ́ Jésù náà ṣe gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là. (Ẹk 12:12, 13) Bákan náà, wọn ò fọ́ ìkankan nínú egungun ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá. Lọ́nà kan náà, wọn ò fọ́ ìkankan nínú egungun Jésù, bó tilẹ̀ jé pé ohun tí wọ́n máa ń ṣe fáwọn tí wọ́n bá fẹ́ pa nìyẹn.—Ẹk 12:46; Jo 19:31-33, 36.