MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣọ́ra Kó O Má Bàa Tan Irọ́ Kálẹ̀
Lónìí, kíákíá ni ìròyìn máa ń tàn kálẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gba ìròyìn látorí rédíò, tẹlifíṣọ̀n, íńtánẹ́ẹ̀tì àti lórí àwọn ìwé tí wọ́n tẹ̀ jáde. Àwa tá à ń sin “Ọlọ́run òtítọ́” kì í fẹ́ tan irọ́ kálẹ̀, kódà a kì í fẹ́ kó ṣèèṣì ṣẹlẹ̀. (Sm 31:5; Ẹk 23:1) Ó léwu gan-an téèyàn bá fi ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́ ránṣẹ́ sáwọn míì. Tó o bá fẹ́ mọ̀ bóyá ọ̀rọ̀ kan jóòótọ́, o lè bi ara rẹ̀ pé:
‘Ṣé mo gbà pé ẹni tó sọ̀rọ̀ yìí ò lè parọ́ fún mi?’ Ẹni tó ń sọ ọ̀rọ̀ yẹn lè má mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀. Àwọn èèyàn sábà máa ń fi kún ọ̀rọ̀ bó bá ṣe ń lọ látọ̀dọ̀ ẹnì kan sí òmíì, torí náà ṣọ́ra tó ò bá ti mọ ibi tọ́rọ̀ náà ti wá. Àwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ máa ń ní ọ̀pọ̀ ìsọfúnni lọ́wọ́, torí náà ó yẹ kí wọ́n ṣọ́ra gan-an kí wọ́n má bàa tan ìsọfúnni tí kì í ṣòótọ́ kálẹ̀
‘Ṣé ọ̀rọ̀ náà lè ba ẹnì kan lórúkọ jẹ́?’ Tọ́rọ̀ náà bá máa mú káwọn èèyàn máa fojú tí ò dáa wo ẹnì kan tàbí àwọn kan, á dáa kó o má sọ̀rọ̀ náà fún ẹnikẹ́ni.—Owe 18:8; Flp 4:8
‘Ṣé ọ̀rọ̀ náà ṣeé gbà gbọ́?’ Ṣọ́ra tó o bá ń gbọ́ ìròyìn tàbí àwọn ìrírí tó ń ṣeni ní kàyéfì
WO FÍDÍÒ NÁÀ BÁWO NI MO ṢE LÈ YẸRA FÚN ÒFÓFÓ? LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Bó ṣe wà nínú Òwe 12:18, ewu wo ni ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè fà?
Báwo ni Fílípì 2:4 ṣe jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe tá a bá ń sọ̀rọ̀ àwọn míì?
Kí ló yẹ ká ṣe táwọn èèyàn bá ń sọ̀rọ̀ ẹnì kan láìdáa?
Kó o tó sọ̀rọ̀ ẹnì kan lẹ́yìn, àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kó o bi ara rẹ̀?