ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 1-3
Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Mú Ọrẹ Wá
Ẹbọ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rú máa ń múnú Jèhófà dùn, ó sì ń ṣàpẹẹrẹ ìràpadà tí Jésù san láti ṣe aráyé láǹfààní.—Heb 8:3-5; 9:9; 10:5-10.
Ẹran tára ẹ̀ dá ṣáṣá ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi rúbọ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìràpadà Jésù ṣe pé, tí kò sì lábàwọ́n.—1Pe 1:18, 19
Tẹ́nì kan bá fẹ́ fi ẹran kan rú ẹbọ sísun, ṣe ló máa fún Jèhófà ní gbogbo ẹ̀ pátápátá, bẹ́ẹ̀ ni Jésù ṣe fi gbogbo ara ẹ̀ rúbọ fún Jèhófà
Kí Jèhófà tó lè tẹ́wọ́ gba ẹbọ ìrẹ́pọ̀ lọ́wọ́ ẹnì kan, ẹni náà gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ẹni àmì òróró tó máa ń jẹ́ ohun ìṣàpẹẹrẹ níbi Ìrántí Ikú Kristi ṣe ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run