ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb21 March ojú ìwé 9
  • Má Ṣe Fara Wé Àwọn Aláìdúróṣinṣin

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Ṣe Fara Wé Àwọn Aláìdúróṣinṣin
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkojú Ìpènijà Ìdúróṣinṣin
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • “Ìwọ Nìkan Ni Adúróṣinṣin”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Fífi Ìdúróṣinṣin Sìn Pẹ̀lú Ètò Àjọ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Kíyè Sí Àwọn Adúróṣinṣin!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
mwb21 March ojú ìwé 9
Ilẹ̀ lanu, ó sì gbé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ mì.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Má Ṣe Fara Wé Àwọn Aláìdúróṣinṣin

Kórà, Dátánì àti Ábírámù ò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ètò tí Jèhófà ṣe, ìyẹn sì fi hàn pé wọn kì í ṣe adúróṣinṣin. Jèhófà pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run, títí kan gbogbo àwọn tó tì wọ́n lẹ́yìn. (Nọ 16:​26, 27, 31-33) Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé ká jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà? Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin?

WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁ ṢE FARA WÉ ÀWỌN ALÁÌDÚRÓṢINṢIN, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Má Ṣe Fara Wé Àwọn Aláìdúróṣinṣin.’ Nadia ń ro ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tóun bá lọ síbi àríyá aláriwo, tí ẹnì kan sì fún òun ní ọtí líle.

    Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Nadia tó dán an wò, àpẹẹrẹ wo ló sì rí nínú Bíbélì tó ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Má Ṣe Fara Wé Àwọn Aláìdúróṣinṣin.’ Arákùnrin kan ń ronú nípa ohun tó ń múnú bí i.

    Kí ló mú kí arákùnrin kan bínú sí àwọn alàgbà, àpẹẹrẹ wo ló sì rí nínú Bíbélì tó ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Má Ṣe Fara Wé Àwọn Aláìdúróṣinṣin.’ Terrance ń ro ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí òun àti arábìnrin kan tóun àti ọkọ ẹ̀ kọ ara wọn sílẹ̀ bá ń dá nìkan wà níbi ìgbọ́kọ̀sí nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.

    Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Terrance tó dán an wò, àpẹẹrẹ wo ló sì rí nínú Bíbélì tó ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Má Ṣe Fara Wé Àwọn Aláìdúróṣinṣin.’ Ọ̀dọ́kùnrin kan ń rò ó bóyá kóun lọ sórí ìkànnì tí wọ́n ti ń ta tẹ́tẹ́ tẹ́nì kan fi ránṣẹ́ sí i.

    Kí ló ṣẹlẹ̀ nílé ìwé tó dán arákùnrin kan wò, àpẹẹrẹ wo ló sì rí nínú Bíbélì tó ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́