TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀
Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Yẹra fún Ẹgbẹ́ Búburú
Kí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, wọ́n gbọ́dọ̀ yan àwọn ọ̀rẹ́ gidi. (Sm 15:1, 4) Àwọn ọ̀rẹ́ gidi máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun tó tọ́.—Owe 13:20; lff ẹ̀kọ́ 48.
Kó o tó lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹ lọ́wọ́ láti yẹra fún ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́, o gbọ́dọ̀ máa fọ̀rọ̀ ro ara ẹ wò. Ó lè má rọrùn fún wọ́n láti fi àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ní nínú ayé sílẹ̀. Torí náà, á dáa kó o máa fìfẹ́ hàn sí wọn kódà láwọn ọjọ́ tẹ ò ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Lára àwọn nǹkan tó o lè ṣe ni pé kó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí wọ́n tàbí kó o pè wọ́n, o sì lè ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn. Báwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹ ṣe ń tẹ̀ síwájú, o lè pè wọ́n sáwọn ìkórajọ táwọn ará bá ṣètò. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n rí i pé ohun táwọn á jèrè kọjá ohun táwọn máa pàdánù. (Mk 10:29, 30) Inú tìẹ náà máa dùn bó o ṣe ń rí i bí àwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń pọ̀ sí i.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ RAN ÀWỌN TÓ Ò Ń KỌ́ LẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ LỌ́WỌ́ LÁTI YẸRA FÚN ẸGBẸ́ BÚBURÚ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Àwọn wo la lè pè ní ẹgbẹ́ búburú?—1Kọ 15:33
Kí ni Jade rò nípa bí ìkórajọ àwa Kristeni ṣe máa rí?
Kí ni Neeta ṣe kí Jade lè fi àwọn ọ̀rẹ́ inú ayé sílẹ̀ kó sì láwọn ọ̀rẹ́ gidi?