ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb22 January ojú ìwé 9
  • Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Wá Sípàdé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Wá Sípàdé
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àǹfààní Tó O Máa Rí Ní Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Ní Àjọṣe Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Yẹra fún Ẹgbẹ́ Búburú
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Jáwọ́ Nínú Ìwà Àìmọ́
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
mwb22 January ojú ìwé 9

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀

Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Wá Sípàdé

Apá pàtàkì lára ìjọsìn mímọ́ ni àwọn ìpàdé wa jẹ́. (Sm 22:22) Gbogbo àwọn tó bá kóra jọ láti jọ́sìn Jèhófà máa láyọ̀, wọ́n á sì rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà. (Sm 65:4) Àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa túbọ̀ tẹ̀ síwájú tí wọ́n bá ń wá sípàdé déédéé.

Kí lo lè ṣe kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè máa wá sípàdé? Máa pè é wá sípàdé látìgbàdégbà. Jẹ́ kó wo fídíò náà Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? Jẹ́ kó mọ àwọn nǹkan tó máa gbádùn tó bá wá sípàdé. (lff ẹ̀kọ́ 10) O lè sọ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tó o kọ́ ní ìpàdé tẹ́ ẹ ṣe kọjá tàbí kẹ́ ẹ jọ ṣàyẹ̀wò ohun tẹ́ ẹ máa kọ́ nípàdé tó ń bọ̀. Fún akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ní ìwé tẹ́ ẹ máa lò nípàdé. Yàtọ̀ síyẹn, o lè ràn án lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, o lè ṣètò láti gbé e wá sípàdé. Tí akẹ́kọ̀ọ́ ẹ bá wá sípàdé fún ìgbà àkọ́kọ́, wàá rí i pé ìsapá ẹ ò já sásán.​—1Kọ 14:24, 25.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ RAN ÀWỌN TÓ Ò Ń KỌ́ LẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ LỌ́WỌ́ LÁTI MÁA WÁ SÍPÀDÉ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Fọ́tò kan látinú fídíò “Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Wá Sípàdé.” Neeta pé Jade wá sípàdé.

    Àǹfààní wo ni Neeta lò láti pe Jade wá sípàdé?

  • Fọ́tò kan látinú fídíò “Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Wá Sípàdé.” Neeta ń rẹ́rìn-ín sí Jade bó ṣe jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ nípàdé.

    Kí nìdí tí inú wa fi máa ń dùn tí akẹ́kọ̀ọ́ wa bá wá sípàdé?

  • Fọ́tò kan látinú fídíò “Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ́wọ́ Láti Máa Wá Sípàdé.” Àwọn arábìnrin kan ń kí Jade lẹ́yìn ìpàdé.

    “Ọlọ́run wà láàárín yín lóòótọ́”

    Kí ni Jade rí nígbà tó kọ́kọ́ wá sípàdé?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́