MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI | OHUN TÓ O LÈ FI ṢE ÀFOJÚSÙN NÍ ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN TÓ Ń BỌ̀
Lọ Síbi Tí Àìní Pọ̀ Sí
Ó gba ìgbàgbọ́ kéèyàn tó lè fi àdúgbò tó ti mọ́ ọn lára sílẹ̀ kó sì lọ síbòmíì kó lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Heb 11:8-10) Tó bá wù ẹ́ láti lọ sìn níbi tí àìní pọ̀ sí, sọ fáwọn alàgbà ìjọ ẹ. Àmọ́ àwọn nǹkan pàtó wo lo lè ṣe kó o lè mọ̀ bóyá àfojúsùn tọ́wọ́ ẹ̀ lè bà ni? Ka àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tó yẹ kéèyàn fi sọ́kàn tó bá fẹ́ lọ sìn níbi tí àìní pọ̀ sí. Yàtọ̀ síyẹn, fọ̀rọ̀ lọ àwọn tó ń sìn níbi tí àìní wà. (Owe 15:22) Bákan náà, gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ ẹ sọ́nà. (Jem 1:5) Ṣèwádìí nípa ibi tó o fẹ́ lọ, tó bá sì ṣeé ṣe, lọ lo ọjọ́ mélòó kan níbẹ̀ kó o tó pinnu láti kó lọ pátápátá.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ ÌGBÀGBỌ́ MÚ KÓ O ṢE PÚPỌ̀ SÍ I—LỌ SÍBI TÍ ÀÌNÍ PỌ̀ SÍ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí ló mú kó ṣòro fún Gabriel láti lọ síbi tí àìní wà, kí ló sì ràn án lọ́wọ́?