“Ṣé Kí N Ṣí Lọ Síbòmíràn?”
1 Láti ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jésù pa pé “ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,” ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti ṣèyàsímímọ́ ló ti ṣí lọ láti sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. (Mát. 28:19) Ńṣe ni wọ́n ń ṣàfarawé Pọ́ọ̀lù, tó dáhùn ìpè náà pé: “Rékọjá wá sí Makedóníà, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.” (Ìṣe 16:9) Báwo la ṣe lè ṣe èyí lọ́nà tó wúlò?
2 Ohun Kan Ni Kí O Ṣe Lẹ́ẹ̀kan: Ṣé ìpínlẹ̀ tí ẹ kì í ṣe déédéé wà tó jẹ́ ti ìjọ yín? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè darí ìsapá rẹ sí àwọn àgbègbè yẹn. Kí o tó pinnu láti ṣí lọ síbòmíràn, bá àwọn alàgbà rẹ fikùnlukùn láti mọ̀ bí wọ́n bá rò pé o ti gbára dì tó láti ṣí lọ. O tún lè béèrè lọ́wọ́ alábòójútó àyíká rẹ bóyá ó mọ ìjọ kan tó wà ní tòsí, níbi tí o ti lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i. Yàtọ̀ sí ìyẹn, lẹ́yìn tí o bá ti fara balẹ̀ ṣírò ohun tí yóò ná ọ, o lè fẹ́ láti ronú nípa ṣíṣèrànwọ́ ní apá ibòmíràn lórílẹ̀-èdè rẹ tàbí lórílẹ̀-èdè mìíràn. Bí o bá fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, kí ìwọ àti ẹgbẹ́ àwọn alàgbà rẹ kọ̀wé sí iléeṣẹ́ ẹ̀ka ibi tí o ti fẹ́ láti sìn, kí o ṣàlàyé àwọn ohun tí o ti gbé ṣe látẹ̀yìnwá nínú iṣẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. Yóò bọ́gbọ́n mu pé kí o kọ́kọ́ ṣèbẹ̀wò sí àgbègbè yẹn ná kí o tó pinnu bóyá wàá ṣí lọ pátápátá tàbí o kò ní ṣí lọ.
3 Kíyè Sára Ni Ti Ṣíṣí Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Mìíràn: Àwọn ará wa tó ń ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn nítorí pé wọ́n ń wá ibi tí ọ̀ràn àtijẹ àtimu yóò ti túbọ̀ rọrùn tàbí nítorí kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ ìnilára túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Bí wọ́n ti ń ṣe èyí, àwọn kan ti bọ́ sọ́wọ́ àwọn alágbèédá tí wọ́n ṣèlérí pé àwọn yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa gbé ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ náà, ṣùgbọ́n ńṣe ni wọ́n gbowó lọ́wọ́ wọn, tí wọ́n sì pa wọ́n tì. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn èèyàn wọ̀nyẹn tilẹ̀ máa ń gbìyànjú láti fipá mú àwọn tó ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn yìí láti máa ṣe ìṣekúṣe. Nígbà tí wọ́n bá kọ̀, wọ́n á jẹ́ kí wọ́n há sọ́wọ́ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣí lọ náà. Nípa báyìí, ọ̀ràn àwọn aṣíwọ̀lú yẹn á wá burú ju ìgbà tí wọ́n wà ní ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn lọ. Ó tilẹ̀ lè di dandan pé kí wọ́n bẹ àwọn ará láti gbà wọ́n sílé, kí wọ́n sì tún ṣèrànwọ́ fún wọ́n nígbà mìíràn pẹ̀lú, tí wọ́n á tipa bẹ́ẹ̀ dẹ́rù pa àwọn ìdílé Kristẹni mìíràn tí àwọn náà ń dojú kọ wàhálà àti ìṣòro tiwọn. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé kan kò bá ara wọn gbé mọ́, àwọn ìdílé kan sì ti di aláìlera nípa tẹ̀mí nítorí ṣíṣí tí wọ́n ṣí lọ lọ́nà tí kò bọ́gbọ́n mu bẹ́ẹ̀.—1 Tím. 6:8-11.
4 Bó bá jẹ́ pé fún àǹfààní ti ara rẹ lo ṣe fẹ́ ṣí lọ, fi sọ́kàn pé ibi yòówù kí o máa gbé, ìṣòro wà tí wàá dojú kọ. Ó túbọ̀ rọrùn láti borí àwọn ìṣòro níbi tí o ti gbọ́ èdè wọn, tí o sì mọ àṣà wọn tẹ́lẹ̀, ju pé kí o ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ bẹ̀rẹ̀ ní ibi tí o kò mọ̀ tẹ́lẹ̀.