ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb22 July ojú ìwé 16
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Lo Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Bá A Ṣe Lè Fi Àṣàrò Kúkúrú Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Kọ Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tó O Fẹ́ Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
mwb22 July ojú ìwé 16
Fọ́tò: 1. Arábìnrin kan àti ọkọ ẹ̀ ń fi ìwé “Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!​—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì” lọ obìnrin kan nílé ẹ̀. 2. Arábìnrin náà ń lo ìwé “Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!​—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì” ní ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bá A Ṣe Lè Lo Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni ètò Ọlọ́run ń ṣe láti ṣètò àwọn ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ, ọ̀pọ̀ akéde sì ti rí i pé àwọn àbá yẹn gbéṣẹ́ gan-an ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Àmọ́, bí nǹkan ṣe rí lágbègbè kan yàtọ̀ sí òmíì, torí náà àwọn akéde lè lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalè míì tàbí kí wọ́n jíròrò àkòrí míì táwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ sí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì kí gbogbo wa tẹ̀ lé ìtọ́ni èyíkéyìí tí wọ́n bá fún wa nígbà àkànṣe ìwàásù. Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí wa ní bá a ṣe máa pa àṣẹ Jésù mọ́ pé ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.​—Mt 24:14.

Kí àwọn akéde tó bá níṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ jíròrò àkòrí ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Àmọ́ wọ́n lè lo ìbéèrè míì, ẹsẹ Bíbélì míì tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ míì tó máa gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn, àyàfi tí ìtọ́ni bá sọ pé kí wọ́n lo èyí tó wà nínú ìwé ìpàdé. Ìtọ́ni yìí là á máa tẹ̀ lé dípò èyí tó wà ní ojú ìwé 8 nínú ìwé ìpàdé June 2020.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́