Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù yìí lọ, kò ní sí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ apá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a máa ń ṣe ní ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ mọ́. Dípò ìyẹn, Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ máa ní apá kan tá a pè ní ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lábẹ́ rẹ̀, a máa rí ìbéèrè kan tá a lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò, ẹsẹ Bíbélì tá a máa kà, àti ìbéèrè fún ìgbà míì. Ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, fídíò kan la ó máa wò ní apá “Máa Lo Ara Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù.” Akéde kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí fídíò tó máa lò àti ìgbà tó máa lò ó, bóyá nígbà àkọ́kọ́ tàbí nígba ìpadàbẹ̀wò. Ní àfikún sí èyí, a máa rí àbá méjì nínú ìwé ìpàdé wa tó máa sọ bá a ṣe lè máa bá ìjíròrò tá a ti bẹ̀rẹ̀ nìṣó. Ọ̀nà tuntun yìí máa jẹ́ ká lè túbọ̀ máa kọ́ “gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.”—Iṣe 13:48.
Iṣẹ́ Ọmọ Ilé Ẹ̀kọ́: Kí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ṣe àṣefihàn àwọn ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ, àfi tí ìtọ́ni bá sọ pé kí wọ́n má ṣe bẹ́ẹ̀.