ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Sólómọ́nì Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Gbàdúrà Látọkàn Wá
Nígbà ayẹyẹ tí wọ́n fi ṣí tẹ́ńpìlì, Sólómọ́nì gbàdúrà àtọkànwá níwájú àwọn èèyàn náà (1Ọb 8:22; w09 11/15 9 ¶9-10)
Sólómọ́nì ò pàfiyèsí sí ara ẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ Jèhófà ló fìyìn fún (1Ọb 8:23, 24)
Sólómọ́nì fi ìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà (1Ọb 8:27; w99 1/15 17 ¶7-8)
Àpẹẹrẹ tó dáa ni Sólómọ́nì fi lélẹ̀ fún gbogbo wa, pàápàá àwọn tó ń ṣojú àwùjọ nínú àdúrà. Kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ wa ṣe dùn létí àwọn èèyàn ló yẹ kó jẹ wá lógún bí kò ṣe bí ohun tá a sọ ṣe rí lára Jèhófà.